Bi Igba Ehin Ijapa Se Fo.
Aalo o aalo, ni igba laelae,
igba kan nlo igba kan nbo igba kan ko lo ile aye gbo. Alo mi dale ori Ijapa . Iyan
mu ni ilu ijapa, to bẹẹ gẹẹ awon ara ilu se ipade bi awon ko se ni ku. Won pinnu lati
sarajo ki gbogbo won lo wa onje ni ilu odikeji. Eni kan ni yio se asoju fun
idile kookan, won o jeun , won o mu, awon asoju yio si ko onje wale fun gbogbo
ebi won. Ilu odikeji yi jinna won ko le rin lo si ibe won nilati fo lo ni. Awon
ẹyẹ da iyẹ kookan
fun awon ti ko le fo, bi ijapa, okẹrẹ , ehoro ati bẹẹbẹẹ lo. Nigbati won de ibi ti won nlo ijapa ba awon iyoku re
soro oni .o dara bia bay an oruko tuntun ti awon arailu yio ma pew a ni tori
asa ilu yi ni yen. Onikaluku yan oruko titun. Okere ni ouun ni sare gunigi,
ehoro ni oun ni sarewoiho. Ijapa ni oun o maa jẹ gbogbo yin . Awon ara ilu oke fi tayotayo pade
awon alejo wonyi. Won dari won si aafin
oba. Awon onisẹ oba pon oti, won ro oka . Bi oni sẹ ti ngbe ounjẹ bo ijapa sare pade rẹe ogba onjẹ lowo rẹ osi nnikan je. O so fun awon ore re ti won jo
wa wipe ounje toun ni. Ope onise oba pada osi bere lowo rẹ pe ounjẹ tani eleyi? Onisẹ oba da hun wipe ounjẹ ti
gbogbo yin ni. Won gbe mimu wa ijapa si tun se bẹẹ. Igba
ti ilẹ su ijapa di eyi to sẹku
ninu ounjẹ osi so fun awo n ẹlẹgbẹ rẹ pe ile ya. Ebi pa okẹrẹ, ori rẹ le
koko , ebi pa ehoro , eyin rẹ pa keke, ebi pa ẹyẹ ga o rojo, ebi pa asa o ra baba , ebi
pa atiala o sokun, abi pa aparo o pose ,
ebi pa owiwi ,o moju. Won bo sona won nfo pada bo wa’le ijapa ba dahun oni awon
ilu yi dara pupo, ẹ jẹ ki a
maa wa lẹẹkan l’osẹ. Ka jẹun ka
yo batakun. Inu awon ẹyẹ ko
dun lati gbo roro ti ijapa so nitori won ko jẹ oun
kaknkan. Won binu onikaluku gba iyẹ ẹyokan
rẹ lara ija pa . Gbogbo wa la mo wipe Ijapa ko le fo, ijapa
jabo silẹ lati oju orun, igba ẹyin
re si fo ka yanga. Awon eera lo pejo ti won sa igbare ti won sit un to. I gba
ijapa ti di woko woko lati igba naa.
Itan yi ko wa pe ki a ma se hu iwa wobia si omonikeji wa.