Kiniun jẹ Ọba ni ilu awon ẹranko. Iyan mu gidigidi, ojo ko rỌ fun Ọdun mẹta gbako. Gbogbo igi igbo gbẹ, eweko jona mỌlẹ awỌn ẹranko kosi ri ounjẹ jẹ deede. Iyan yi le de bi pe Kiniun Ọba gan ko ri ounjẹ jẹ deede. Ọkan Ọba bajẹ, o si ṣaarẹ. O ranṣẹ pe adahunṣe.
Adahunṣe de, o ki kabiyesi o si wipe Ọba ni lati ṣe etutu, ki ilu le toro ni oju aye rẹ. Odidi erin ni ao fi rubỌ, niwaju aafin laarin ilu. Eyi ni wipe wỌn yio mu erin wa si aafin, ni aaye lati fi ṣe etutu.
Ọba mi kan lẹ o ni iyẹn ko le ṣeeṣe. Bawo ni ao ṣe mu erin wỌ’lu. Tani yio mu erin wỌ’lu. Lẹhin igba ti erin ba wỌ ilu tan tani yio le pa erin. Adahunṣe ni bi wỌn ba ti ri erin ki wỌn ranṣe si oun lati ṣe etutu.
Ọkan Ọba rẹwẹsi, osi ke si iyawỌ rẹ pe , bawo ni oun yio ṣe ṣe etutu yi? Iyawo rẹ ni ko sỌ fun awỌn ijoye ki wỌn o yan Ọdẹ aperin lati lỌ mu erin wa. Ọdẹ apeerin wipe erin ko le ṣee mu laaye.
Ọba ni ki akede ke si gbogbo ara ilu wipe ẹnikeni ti o ba le mu erin wỌ ilu laaye ti oun yio fi ṣe etutu, oun o fun ni ỌmỌbinrin ohun lati fi ṣ’aya pẹlu dukia lỌpỌlỌpỌ.
Ijapa gbỌ
akede, o da gbere fun iyawo re Yannibo oni, “mo ti fẹ iyawo le Ọ,
ỌmỌ
Ọba si ni”. Yannibo bu si ẹrin
oni, “boo ba tan ara rẹ tan, ko wa irỌ mi pa”.
Ijapa gbera o di aafin, o ba ỌpỌlỌpỌ
jagunjagun ti wỌn
ti de ṣiwaju rẹ. Olukaluku a wỌle
s’iwaju Ọba, wỌn
si sỌ gbogbo bi awon oṣe dẹ okun mu erin, ṣugbon o ku bi wỌn
yio ṣe faa wỌ ilu laaye. Ẹlomiran ni oun o fun
eerin ni ogun orun, oun yio si gbe wỌ
ilu, ṣugbỌn
ori ajanaku kii ṣe ẹru ỌmỌde, erin ko ṣe e gbe.
Ni paripari o ṣẹku
ijapa nikan. Ilẹ ti ṣu, Ijapa ti sun lỌ osi nhan run. AwỌn ijoye ji i. O wỌle siwaju Ọba
oni ‘Ao merin j’Ọba
... ẹwẹtu ẹwẹlẹ’, ao m’erin jỌba
ẹwẹtu ẹwẹlẹ. AwỌn
ẹmẹsẹ fa ida yỌ
wỌn fẹẹ
pa ijapa . Ijapa sỌrỌ oni orin ti ẹ o ma kỌ
l’ỌjỌ
mẹta si isinyi niyẹn. A o gbẹ koto nla si iwaju aafin a o da ẹni bo, a o wa gbe aga Ọba lee. Gbogbo ara ilu yio ko si asỌ ẹyẹ, wỌn
o ma ṣe ayẹyẹ.
Emi o lỌ si ibudo erin ngo si lỌ sỌ fun wipe ati le kiniun Ọba kuro l’ori itẹ. Oun erin l’okan ti ao fi jẹ Ọba wa. Gbogbo awỌn ỌjỌgbỌn fori kori wỌn si wipe, kosi oun to dara to ỌgbỌn ti ijapa mu wa. Kabiyesi faramỌ ete ijapa.
Ni ỌjỌ kẹta, ijapa ati onilu gbera wỌn lỌ si ibudo erin. Bi ijapa ṣe ri erin lỌkankan o bu si orin oni: ‘A o m’erin jỌba’, awon onilu ba ngbee pe ‘ẹwẹtu ẹwẹlẹ’.
Ao
m’erin j’Ọba..... ẹwẹtu ẹwẹlẹ
Ọba
alade,...............ẹwẹtu ẹwẹlẹ
Ao m’erin j’Ọba......
ẹwẹtu ẹwẹlẹ
‘A o m’erin jỌba’, awon ara ilu ba ngbe pe ‘ẹwẹtu ẹwẹlẹ’.
Ao m’erin j’Ọba........ ẹwẹtu ẹwẹlẹ
Ọba
alade,................ ẹwẹtu ẹwẹlẹ
Ao m’erin j’Ọba........
ẹwẹtu ẹwẹlẹ
Gbogbo won fi t’ijo t’ayỌ tẹ le
ijapa ati erin lỌ
si ori itẹ kabiyesi rẹ. Bi erin ṣe
joko si ori aga gbogbo ẹni jin si isalẹ, erin ja si koto, adahunse fi erin ṣe etutu. Ojo bẹrẹ si rỌ,
eweko ntutu minijỌjỌ, gbogbo ẹranko
njẹun, ilu si toro. Ara kiniun Ọba ya gaga, O fi ỌmỌbinrin
rẹ fun ijapa ko fi ṣe aya. O fun ni dukia rẹpẹtẹ. Ijapa si di ana Ọba.
Ijapa ,the tortoise is considered most cunning among all animals because of the mystery of it's long life, also because it moves so slowly. Tortoises have been known to live over a hundred years. Unlike keeping goats and chickens, which very soon the owner could eat or sell, the tortoise is kept out of love for the animal. Great men keep tortoises in their compounds. A good example is the Tortoise in the Soun's palace at Ogbomosho, Nigeria. The Yoruba folklores refer to the tortoise severally as being cunning, greedy, wise etc.
ReplyDelete